Ureacycle (tí wọ́n tún mọ̀ sí ìpòyìornithine) jẹ́ ìpòyì àwọn ìbáṣepọ̀ kẹ́míkà àgọ́ ara tí ó má a ń ṣẹlẹ̀ lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹranko tí ó máa ń jẹ́ kí urea ((NH2)2CO) jade láti inú ammonia (NH3). Ìyípo yìí jẹ́ ìpòyì ìbáṣepọ̀ kẹ́míkà àgọ́ ara àkọ́kọ́ tí wọ́n máa kọ́kọ́ ṣàwárí (Hans Krebs àti Kurt Henseleit, 1932), ní ọdún marún sẹ́yìn kí wọ́n tó ṣàwárí Ìyípo TCA.[1] Ní àwọn ẹranko tó lè bímọ, ìyípo urea máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹ̀dọ̀, bíi díẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ nínú kídìrín.
Àwọn oun ẹlẹ́mí tí kò rọrùn fún láti yọ ammonia kúrò lára máa ń sọọ́ dí àwọn nkan míràn bíi urea tàbí uric acid, tí kò ní májèlé púpọ̀.[2] Àìtó ìyípo urea yìí máa ń wáyé látàrí àṣìṣe ìbínimọ́ (àṣìṣe ìbínimọ̀ nínú ara), àti tí ẹ̀dọ̀ bá dáwọ́ iṣẹ́ dúró. Èsì ìdáwọ́ iṣẹ́ ẹ̀dọ̀ dúró ní ìkójọpọ̀ àwọn ẹ̀gbin tí ó ní ṣe pẹ̀lú nitogen, pàtàkì jùlọ ammonia, tí ó máa ń fa ààrùn hepatic encephalopathy.
Ìyípo urea ní àwọn ìbáṣepọ̀ marún: méjì ń ṣẹlẹ̀ nínú mitochondra tí mẹ́ta sì ń ṣẹlẹ̀ nínú cytosol. Ìyípo yìí máa ń sọ àwọn ẹgbẹ́ amino méjì, ìkan láti NH4+ àti ìkan lati Asp, àti átọ́mù carbon kan láti HCO3−, sí àwọn ẹ̀gbin tí kò ní májèlé urea ní iye "agbára nlá" àwọn àsopọ̀ phosphate ( ATP mẹ́ta tí ó pín sí ADP méjì àti AMP ẹyọ kan). Ornithine ló máa ń gbé àwọn átọ́mù carbon àti nitrogen yìí.
Ní ìbáṣepọ̀ àkọ́kọ́, NH4+ + HCO3− jẹ́ NH3 + CO2 + H2O.
Gbogbo oun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìyípo urea jẹ́:
NH3 + CO2 + aspartate + ATP mẹ́ta+ H2O méjì→ urea + fumarate + ADP méjì+ Pi méjì+ AMP + PPi
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́pé a máa ń rí fumarate tí a bá yọ NH3 kúrò nínú aspartate (nínú ìbáṣepọ̀ kẹta àti ìkẹrin), àti PPi + H2O → Pi méjì, ó lè rọrùn báyìí:
NH3 méjì + CO2 + ATP mẹ́ta + H2O → urea + ADP méjì + Pi mẹ́rin + AMP